Àwọn Ofin Ipìlẹ ̀Sunnah ti Imām Al-Ḥumaydi
Ni orúkọ Allāh, Àjọkẹ́ Ayé, Àṣàkẹ́Ọ̀run.Àwọn òfin ìpìlẹ̀ Sunnah ti Imām Al-ḤumaydiBishr bn Mūsá gba wá fun wa, ó sọ pé: Al-Ḥumaydi gba wá fun wa, ó sọ pé:Sunnah ni ọdọ wa, òhun ni ki èèyàn gbàgbọ́ ninu kádàrá—dáadáa rẹ̀, àti búburú rẹ— dídùn rẹ, àti kíkorò rẹ. Ki o si mọ pé, ohun ti o ba ba, kòsí làkọsílẹ̀ pé yóò tàsé rẹ, ohun ...