Ẹyín lè ti máa gbọ, tàbí kí ẹti rí bí àwọn Ahlu Sunnah ṣé máa n’kìlò fún àwọn èèyàn kúrò níbi Bídíàh (àdádáálẹ ẹsìn), ṣùgbọn tí ẹ kò mọ ohun tí wón pèní Bídíàh àti ìdí tí wọ n’fín sọ wípé kò da.
Gbólóhùn “Bídíàh” jẹ èdè lárúbáwá, tí ìtumọ rẹ jẹ “àdádáálẹ inú ẹsìn”. Ìyẹn ni àwọn ohun tí kò sí lára ẹsìn láyé Ànnábì, ﷺ, bẹẹ sì ni kòsí lára ẹsìn láyé àwọn Sàábé Ànábì, ṣùgbón tí àwọn èèyàn n pè lẹsìn láyé òde òní.
Èèyàn lè ma bèèrè wípé, ọpọlọpọ nkan ni wọn kò lò láyé Ànnábì, ﷺ, ṣùgbón tí àán lò láyé òde-òní, Ànnábì kò wa mọtò, béẹni kò gun ọkadà, ṣé a máa wá pe mótò gígùn àti ìmáagun Ọkadà ní Bídíàh ni? Rárá, a kò ní pè wọn ní Bídíàh, nítorí wípé wọn kò kín ṣe ọrọ ẹsìn. Àwọn ohun tí àn pè ní Bídíàh ni àwọn ohun tí àwọn Mùsùlùmí mú ní ìjosìn, tí wọn kò sì sí lára ìjosìn tẹlẹ.
Fún àpẹẹrẹ, Ìrun rákà méjì ni aa máa ń kí ní ìrun Àsùbáà, kí a wá rí ẹnìkan tó rò wípé òhún ṣẹsẹ jí ní àárọ ni, òhún sì ní agbára láti kí ju rákà méjì lọ, òhún sì máa kí rákà mẹfà, irú ohun tí ènìyàn yíì ṣe jẹ ìjosìn tí Ànnábì ﷺ kò ṣe, tí àwọn Sàábé Ànnábì kò ṣe, irúfẹ nkan báyìí ni à ń pè ní Bídíàh, nítorí wípé ó jẹ àdádáálẹ ẹsìn.
Atúnlè ṣàlàyé Bídíàh wípé ó jẹ ohun tí àwọn èèyàn ńpè ní ìjosìn, ṣùgbón tí kò ní ẹrí kan láti inú Al-Qurʾān, bẹẹ ni kò sì ní ẹrí kan láti inú Sunnah Ànnábì, irúfé nkan báyìí ni à ń pè ní Bídíàh.
Allāh pa àwa Mùsùlùmí láṣẹ wípé ká mú ẹsìn wa láti inú Qurʾān àti Sunnah Ànnábì ni, kò wí fún wa wípé ká máa gbé ẹsìn kalẹ fún raawa pẹlú ìfẹ inú, ẹni tí ó ngbé àdádáálẹ sínú ẹsìn, tí ón ṣe nkan tí Ànnábì àti àwọn Sàábé rẹ kò ṣe nínú ẹsìn, irú ẹni bẹẹ n tẹlé ìfẹ inú rẹ ní. Allāh sọ wípé:
وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّنِ ٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ بِغَيْرِ هُدًى مِّنَ ٱللَّهِ
“Ta ló fín sọnù tó ẹni tón tẹlé ìfẹ inú rẹ, láì sí ìmọnà láti ọdọ Allāh” [Suratul Kọsọs: 50]
Lára aburú tó lágbára tó wà lára ìmaaṣe Bídíàh ni wípé; Ẹni tó nṣe nkan tí kòsí nínú ẹsìn nsọ wípé ẹsìn kò pé nìyen. Ó sì túmọ sí wípé, Ànnábì, ﷺ, kò jíṣẹ pé. Òhún ríi wípé ó yẹ kí nkan t’òhun ṣe yẹn wà nínú ẹsìn, ìgbà tí kò sì ti sí nínú ẹsìn, ìdí nìyẹn tí òhun fi fikúun fún ara òhun. Kódà kí ẹni t’ó n ṣe Bídíàh má sọ eléyìí síta, eléyìí ni nkan tí iṣẹ rẹ n túmọ sí. Ká ní lòòótọ ni ó gbà wípé ẹsìn pé ni, kò ní fi nkan tuntun kúun.
Nígbàtí ó kù díẹ kí Ànnábì ﷺ kú, Allāh ránṣẹ sí Ànnábì ﷺ ní ọjọ Àràfááh, Allāh sọ wípé:
الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ الْإِسْلَامَ دِينًا
“Mo ṣe ẹsìn yín ní pípé fún yín lónìí, mo sì ṣe àṣepé ìdẹra mi fún yín, mo sì yọnú sí Islām ní ẹsìn fúun yín.” [Suratul Mọọ’idah:3]
Ááyàh yìí tọkaa fún wa wípé ẹsìn Islam ti pé, ohun tí kò bá sí lára ẹsìn Islām ní ọjọ tí Allāh sọ wípé ẹsìn ti pé, irú nkan bẹẹ kò lè sí lára ẹsìn láíláí. Ní ọjọ tí Allāh sọ ááyàh yìí kalẹ, ìmaa ṣe ayẹyẹ Màòlúúdì kò sí lára ẹsìn nígbà náà, eléyìí tó túnmọ sí wípé kò le sí lára ẹsìn títí láíláí. Bídíàh ni irú nkan bẹẹ.
Ànnábì ﷺ ti sọ nínu Ḥadīth wípé “Ẹ ṣọ ra fún àwọn nkan tuntun tí wón bá gbéwọ inú ẹsìn, nítorí gbogbo nkan tuntun tí wón bá gbé wọ inú ẹsìn ni àdádáálẹ, gbogbo àdádáálẹ sì nì yí, anù ni, gbogbo anù sì ló wà nínu iná.”
Ìyá wa ʿĀʾishah náà tún gbàá wá wípé, Ànnábì ﷺ sọ wípé: “Eni tó bá gbé nkan titun sínú àlámàrí wa yìí (ẹsìn Islām), eléyìí tí kò sí ní bẹ tẹlẹ, wón á dáapadà.” Ìyẹn ni wípé, Allāh kò ní tẹwọ gba iṣẹ Bídíàh. Tí èèyàn báti mọ wípé, iṣẹ Bídíàh ni iṣẹ kan, tí Allāh kò sì ní tẹwọ gbáà lówọ rẹ, Kíni ènìyàn kúkú nṣe irú iṣẹ náà síí?!
Eléyìí ntọka sí ìdí tí Shayṭan fi níìfé kí àwọn ọmọ ènìyàn máa ṣe àdádáálẹ nínu ẹsìn, ó mọ wípé tí wón bá n ṣe Bídíàh, wón á máa dunú, wón á ma lérò wípé àwọn n sin Allāh ni, tí wọn kò sì mò wípé Allāh kò ní tẹwọ gbà á, bí kòṣe wípé Allah á tún fi ìyà jẹ ẹni t’ó bá ṣe àdádáálẹ sínu ẹsìn. Ó di ọjọ alẹ kí alábùradà tó mọ wípé ẹrù ni òhún rù.
Ó di ọjọ al-Qiyaamah kí oní Bídíàh tó ríi wípé, gbogbo ìjọsìn Bídíàh tí òhun ti tì síwájú, tó rò wípé Allāh máa sán lẹsan, àṣé asán ni gbogbo rẹ. Kò sì ní gba ẹsan kankan lóri rẹ. Kí Allāh má ṣe jẹkí ọrọ wa já sí asán.
Shayṭān ní ìfẹ sí kí ọmọ ènìyàn máa ṣe Bídíàh lọpọlọpọ. Kó dà, ó nì fẹ sí kí Mùsùlùmí ma ṣe Bídíàh ju kí Mùsùlùmí máa fa igbó tàbí mu ọtí lọ. Mùsùlùmí tó nfa igbó tàbí mu ọtí, mọ wípé ohun tí òhún nṣe kòda, ó lè maa kábàmọ lóri rẹ, tàbí kí ó ma sọ fún àwọn èèyàn kí wọn ṣ’àdúrà fún òhun, kí òhún lè jáwọ. Ṣùgbọn Mùsùlùmí tí ó bá nṣe Bídíàh, yio ma rò wípé òhún nṣe ìjọsìn ni, kódà ó lè ma rí ara rẹ wípé òhún dáa ju àwọn tó kù lọ, kò ní túúbá kúrò níbẹ, ní ṣe ni yio ma ṣe ìyanràn pẹlú rẹ, títí tí yio fi pàdé Allāh, tí yio sì ri wípé, asán ni gbogbo ohun tí òhún gbé ilé ayé ṣe.
Nkan pàtàkì tó yẹ kí a tún wòye sí ni wipe, Àdádáálẹ níbi ẹsìn mán yíí ẹsìn padà kúrò ní bi ẹsìn ti ṣe rí ní ìpìnlẹ ni. Ìdí nìyẹn tí ẹsìn àwọn Kiriyó kò fi papọ. Bí àwọn Kiriyó ti ṣọọṣì Àgùdà ṣe n ṣe ìjọsìn yàtọ sí bí àwọn Kiriyó ajẹẹrí ṣe nṣe tiwọn. Ìjọsìn ìjọ àpóstélì kò jọ ti Babtiísì bẹẹni ni ti Babtiísì kò jọ ti Kérúbù. Ìjọsìn Kérúbù tún yàtọ sí ti Sẹlẹ. Gbogbo wọn yapa ara wọn nígbàtí oníkálukú wọn gbé ẹsìn kúrò lóri bí Allāh ti sọọ kalẹ, tí wọn si n se ẹsìn pẹlú ìfẹ inú wọn. Nígbàtí ìròrí àti ìfẹ inú kú sọtọọtọ, Sẹlẹ kò ní wọ bàtà, Fadá ti ṣọọṣì àgùdà kò ní fẹyàwó, kò sì ní bímoọ, àwọn ajẹẹrí kìí ṣe Kérésì, bẹẹni gbogbo ẹsìn wá yàtọọtọ ní to rí, wọn kò dúró lórí bí Allāh ti sọọ kalẹ. Ó wá di wípé, Kiriyó kò le ṣe ìjọsìn àyàfi tí ó bá dé Ilé ìjọsìn rẹ. Kérúbù kò ní ṣe ìjọsìn pẹlú Sẹlẹ, Sẹlẹ kò ní jọsìn pẹlú Ajẹẹrí, bẹẹni Ajẹẹrí kò ní ṣe pẹlú àwọn Ṣọọṣi Àgùdà.
Eléyìí kò rí báyìí ní ọdọ àwa Mùsùlùmí, bí á se nkírun ni Nàìjíríà, bẹẹ gẹgẹ ni wọn sṣe nkírun ní Sáúdí. Ìrun àwọn ará Sáúdí kò yàtọ sí ti àwọn ará Ṣáínà. Ti Mùsùlùmí kan bá gbéra láti Amẹríkà wá sí ilẹ yíí, kò sí Mósáláásí tí kò ti lè kírun. Kó ní bèèrè wípé “Àwọn ìjọ wo ni nbẹ níbi?” síwájú kó tó kírun. Bákanáà ni gbogbo wa sen kírun. Ṣùgbọn tí àwa Mùsùlùmí kò bá kẹkọ níbi ìpínyẹlẹyẹlẹ àwọn Kiriyó, tí a ó sí dẹkun ìma fi nkan sínú ẹsìn, ó fẹẹ yá, tí ẹsìn wa na ma dà bi tiwọn.
Tí àwọn Mùsùlùmí Amẹríkà bá fi nkankan kún ẹsìn wọn, tí nkan na kòsí nínú ẹsìn tí gbogbo wá mọ, tí wọn bá dé Nàìjíríà, wọn kò ní lè ṣe ẹsìn pẹlú wa. Njẹ tí àwọn ará Ṣáínà bá bẹrẹ sí ní kí Asuba wọn bi Rákà mẹwa, Ṣe ẹma lè kírun pẹlú wọn? Rárá. Ẹwá wo bí kò bá ṣe rí tí oníkálukú bá bẹrẹ sí ní fi nkan kún ẹsìn, báyìí ni gbogbo ẹsìn ṣe máa dàrú, tí kòní jọ ẹsìn ọkan ṣoṣo mọ, tí ìsọkan níbi ẹsìn sì ma sọnù.
Njẹ ẹmọ nkan tí Allāh sọ nípa àwọn tí wọn bá pín ẹsìn wọn yẹlẹyẹlẹ, Allāh sọ wípé:
إِنَّ ٱلَّذِينَ فَرَّقُوا۟ دِينَهُمْ وَكَانُوا۟ شِيَعًا لَّسْتَ مِنْهُمْ فِى شَىْءٍ ۚ إِنَّمَآ أَمْرُهُمْ إِلَى ٱللَّهِ ثُمَّ يُنَبِّئُهُم بِمَا كَانُوا۟ يَفْعَلُونَ
“Dájúdájú àwọn tí wọn pín ẹsìn wọn sí yẹlẹyẹlẹ, tí wọn sì wà ní ìjọ ọtọọtọ, ìwọ (Annabi Muḥammadﷺ) kò ní nkan ṣe pẹlú wọn” [Sūratu Al-Anʿam: 159]
Èyí tọka sí wípé, tí àwọn ènìyàn bá ti nfi nkan kún ẹsìn, tí ó sì ti di wípé oníkálukú nṣe nkan ọtọọtọ nínú ẹsìn, tí ẹsìn ti wá pín yẹlẹyẹlẹ, Annabi kò ní nkan ṣe e pẹlú àwọn tí wọn pín ẹsìn wọn. Ìjọsìn ti èèyàn ba nṣe, ṣùgbọn tí Annabiﷺ kò ní nkan ṣe pẹlú ẹsìn náà, ṣé ìmọnà ni irú Ìjọsìn náà ni tàbí ìṣìnà? ìṣìnà, eléyìí tí kò ní iyè méjì nínú.
Ó tó fún wa ká dúró lóri nkan tí Ànnábì múwá, Ẹsìn ti pé, a kò ní bùkátà láti fi nkankan kún ẹsìn. Allāh ṣe ìlérí ìyà fún ẹni tó bá yapa Ànnábì àti ohun ti àwọn Mùsùlùmí àkọkọ wà lóri rẹ, Allāh sọ wípé:
وَمَن يُشَاقِقِ ٱلرَّسُولَ مِنۢ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُ ٱلْهُدَىٰ وَيَتَّبِعْ غَيْرَ سَبِيلِ ٱلْمُؤْمِنِينَ نُوَلِّهِۦ مَا تَوَلَّىٰ وَنُصْلِهِۦ جَهَنَّمَ ۖ وَسَآءَتْ مَصِيرًا
“Ẹni tí ó bá yapa òjíṣẹ na lẹyìn ìgbà tí ìmọnà ti hàn si, tí ó sì gba ojú ọnà tó yàtọ si ojú ọnà àwọn onígbàgbọ òdodo, a má da ojú rẹ kọ ohun tí ó dojú ara rẹ kọ, a sì ma mú wọ iná Jahannam, ó sì burú ní ìkangun.” [Sūratun Nisāʾ: 115]
Kí Allāh ṣọ wa kúrò níbi iná Jahannam. Kí àwa náà kí à wòye si ìjọsìn tí à n ṣe, ṣe ojú ọnà ti Ànnábì ni tàbí ti àwọn Mùsùlùmí àkọkọ, tí ó bá bá ti Ànnábì mu, kí o máa ṣé lọ. Ṣùgbọn tí kò bá ti bá ti Ànnábì mu, kí o gbe kalẹ, irúfẹ iṣẹ bẹ ni man sọ èèyàn di ẹni iná. Ki Allāh ṣọ wa kúrò níbẹ.
Kí ènìyàn wo Àsàlátù Sunday-Sunday tí ón lọ àti Màòlúúdì tí ón ṣe, Ànnábì, ﷺ, kò ṣeé, bẹẹ sì ni àwọn Sàábé rẹ kò ṣéé. Ó tó fún wa láti gbé àwọn àdádáálẹ yìí kalẹ. A bẹ Allah kí ó ràn wá lọwọ láti lè dúró ṣinṣin lórí Sunnah.
Mubaarak Olayemi Ismail
Abu Muhsinah