Abū Tālib jẹ́ ẹ̀gbọ́n bàbá Ànnábì ﷺ, tí ó sì nífẹ Ànnábi ﷺ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nígbàtí àsìkò ikú Abū Tālib tó, Ànnábi ﷺ lọ sí ọ̀dọ rẹ̀ láti pè wípé kí ó gba Islam kí ó tó kú, Ànnábi sọ fun wípé, “Ìrẹ ẹ̀gbọ́n bàbá mi, sọ wípé “Lā ilāha illa Llāh”, ọ̀rọ̀ tí màá fi ṣe ẹ̀rí fún ọ ní iwájú Allāh”.
Ṣùgbọ́n kàkàkí Abū Tālib sọ gbólóhùn ìgbàlà yìí kì ó tó kú, àwọn kèfèrí méjì kan (Abu Jahl ati ‘Abdullah bn Abi Umayyah) tí wọ́n wà ní ọ̀dọ rẹ̀ sọ fun wípé “Njẹ́ o fẹ́ kọ ẹ̀sìn ‘Abdul Muttalib (ìyẹn bàbá Abu Tālib) kalẹ̀ ni?”
Ànnábì ﷺ tún sọ fún Abu Tālib ní ẹlẹ́ẹ̀kejì wípé, kí ó wí gbólóhùn Lā ilaaha illallah, ṣùgbọ́n àwọ n ọkùnrin kèfèrí méjì yíì o yẹ̀, wọn ò sì gbò, wọ́n dún kokò mọ wípé ṣé yíò gbé ẹ̀sìn bàbá rẹ kalẹ̀ ní. Bayi ni wọ́n ṣe ṣe tí ó sì jẹ́ wípé ohun ìkẹyìn tí Abu Tālib sọ kí ó tó kú ni wípé òhún wà ní o rí ẹ̀sìn ‘Abdul Muttalib, ìyẹn ẹ̀sìn ìmú orogún pẹ̀lú Allah àti ìbọ̀rìṣà.
Tí abá ronú sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí dáadáa, a má ri wípé nkan kan kò mú Abū Tālib kú s’óri ìṣìnà bí kò ṣe wípé ó gbé bàbá rẹ̀ sí ààyè tó ga jù ti Allah lọ nínu ọkàn rẹ̀, ìdí nìyí tí kò fi lè fi ohun tí àwọn bàbá rẹ̀ wa lóri rẹ̀ kalẹ̀ láti tẹ̀lé ojú ọ̀nà Allah.
Bákannáà ó kú sí orí anù tí kò lẹ́gbẹ́ pẹ̀lú wípé ó kú ní kèfèrí nítorí ó bẹ̀rù ohun tí àwọn èèyàn máa sọ ní pa rẹ̀. Nítorí àwọn ògbẹ́ni kèfèrí méjì na kò ní yẹ́ má sọ ọ̀rọ rẹ̀ káàkiri tí ó ba fì le gba ẹ̀sìn Islam, eléyìí jẹ́ ohun tí ó bẹ̀rù tí kò fi gba Islaam kí ó tó kú.
O lèè ma kaanu Abu Tālib lóri ìṣìnà rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ohun tó kóbá Abu Tālib, tí ó sì sọ́ di ẹni tí yíò ṣe gbére nínu iná, àwọn nkan na nda ọ̀pọ̀lọpọ̀ Mùsùlùmí láàmú l’óde òní. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Mùsùlùmí ti gbé àwọn bàbá wọn tí ó ti kọjá lọ sí ipò Allah, tí a bá pé wọ́n kí wọ́n gbé àwọn ìṣesí wọn tó tako sunnah Ànnábi ﷺ kalẹ̀, wọ́n á kọ̀ jálẹ̀, wọ́n á ma sọ wípé àwọn ohun tí àwọn bàbá wọn fi kalẹ̀ ni àwọn yíò máa ṣe.
Allah sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n rí bayi nínu Qur’an wípé:
وَكَذَٰلِكَ مَا أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ فِي قَرْيَةٍ مِنْ نَذِيرٍ إِلَّا قَالَ مُتْرَفُوهَا إِنَّا وَجَدْنَا آبَاءَنَا عَلَىٰ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰ آثَارِهِمْ مُقْتَدُونَ
Bákan náà, Àwa kò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan ṣíwájú rẹ, àyàfi kí àwọn ọlọ́rọ̀ ìlú náà wí pé: “Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa yi o si tẹ̀lé orípa wọn.”
[Zukhruf:23]
Bákannáà, Allah tún sọ wípé:
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ اتَّبِعُوا مَا أَنْزَلَ اللَّهُ قَالُوا بَلْ نَتَّبِعُ مَا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءَنَا ۚ أَوَلَوْ كَانَ الشَّيْطَانُ يَدْعُوهُمْ إِلَىٰ عَذَابِ السَّعِيرِ
Nígbà tí wọ́n bá sì sọ fún wọn wipé: “Ẹ tẹ̀lé ohun tí Allāh sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Rárá! A máa tẹ̀lé ohun tí àwọn bàbá wà wá l’óri rẹ̀” bótilẹ̀jẹ́ wípé Shaytān ń pè wọ́n síbi ìyà Iná tó ń jò fòfò?
[Luqmān: 21]
Tí a bá wòye sí àwọn àáyá Al-Qur’aan tí a mú wá yìí, a rí wípé ìṣesí àwọn aláìmọ̀kan alágídí níí ìkọ ọ̀rọ̀ Allāh kalẹ̀, láti dúró pẹ̀lu ohun tí àwọn bàbá wọn nṣe. O pọn dandan fún gbogbo Mùsùlùmí tòótọ́ láti gbé irú ìṣesí àìmọ̀kan àti agídí kalẹ̀, ká sì tẹ̀lé ojú ọ̀nà Allah.
Tí a bá ti gbọ́ wípé ìwùwàsì wa kan tàbí ìṣesí kan kò bá Qur’an àti Sunnah Ànnábi ﷺ mu, ọ̀ranyàn ni ká gbé nkan na kalẹ̀, ká sì tẹ̀lẹ́ eléyìí tó bá ní ẹ̀rí láti ọdọ Allah àti òjíṣẹ́ rẹ̀.
Kò tọ́ fún Mùsùlùmí láti bẹ̀rù ohun tí àwọn ènìyàn yíò sọ ní pa rẹ̀ tó bá tẹ̀le òdodo ìmọ̀nà láti ọ̀dọ Allah. Ìyọ́nú Allah ni àgbà oore, tí Allah bá ti yọ́nú sí wa, tí a sì mọ̀ wípé awà lọ́rí òdodo, ọ̀rọ̀ ti àwọn ènìyàn yíò sọ nípa wa kò ní kó ìnira kankan bá wa. Ká bẹ̀rù ìgbà tí a ma lò nínu sàárè, ẹnikẹ́ni kò ní wọ inú sàárè pẹ̀lu wa, àyàfi iṣẹ́ olóore wa. Kò sí bí atile pẹ́ láyé tó, ohun tí a ma lo nínu sàárè yíò pẹ ju bẹ́ẹ̀ lọ nínú sàárè. Kílódé tí a o wá máa bẹ̀rù ohun tí àwọn ènìyàn yíò sọ nípa wa tí a bá tẹ̀lé òdodo?!
Allah sọ nípa ọjọ́ Al-Qiyāmah wípé:
يَوْمَ يَفِرُّ الْمَرْءُ مِنْ أَخِيهِ [] وَأُمِّهِ وَأَبِيهِ [] وَصَاحِبَتِهِ وَبَنِيهِ
Ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún ọmọ iya rẹ̀ [] àti ìyá rẹ̀ àti bàbá rẹ̀ [] àti ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
Allah tún sọ wípé:
يَوْمَ لَا يَنْفَعُ مَالٌ وَلَا بَنُونَ [] إِلَّا مَنْ أَتَى اللَّهَ بِقَلْبٍ سَلِيمٍ
Ọjọ́ tí dúkìá kan tàbí àwọn ọmọ kò níí ṣàǹfààní. [] Àyàfi ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ Allah pẹ̀lú ọkàn ti o mọ [Shu‘arā: 88,89]
Gbogbo Mùsùlùmí gbọdọ̀ mọ̀ wípé àwọn ma dúró ní àwọn nì kan ṣoṣo ní iwájú Allah ní ọjọ́ ìdájọ́, l’áìní sí alàgàta tàbí òngbìfọ̀ láàrin àwọn àti Allah, wọ́n á jíṣẹ́ gbogbo ohun tí wọ́n bá gbé ilé aiyé ṣe, kí Mùsùlùmí ronú ọjọ́ nà, kó bi ara rẹ̀ wípé “ṣé tí Allah bá bi mí ní ọjọ́ ìgbénde wípé kílódé tí mi kò fi gbé àwọn Bidiah àdádáálẹ̀ Súfí kalẹ̀, bi àsàlátù, bi máólúdì àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.” Njẹ́ ó ṣeé sọ ní iwájú Allah wípé o kò gbé ojú ọ̀nà Súfí kalẹ̀ ní torí òún bẹ̀rù ohun tí àwọn ènìyàn máa sọ, tí Allah sí ti sọ fún wa nínu Al-Qur’an wípé:
فَلَا تَخَافُوهُمْ وَخَافُونِ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn. Emi ni kí ẹ bẹ̀rù tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. [Aali Imrān: 175]
Ìbẹ̀rù ènìyàn Kò da nkan kan fúnni ní ọjọ́ ìgbénde, ohun tí ó jà jù ní iwájú Allah ni ọkàn tó mọ́ kangá kúrò níbi ìmú orogún pẹ̀lú Allah tí ó sì kún fún Tawheed ati Sunnah, ìyẹn ìmú Allah lọ́kan ṣoṣo ní bi ìjọsìn àti ìtẹ̀lé orípa Ànnábì ﷺ.
Ká mú èkọ́ láti ibi ikú Abū Tālib, ká ṣe ohun tó tọ́ nínú ẹ̀sìn, ká má tẹ̀le àwọn bàbá lóri anù, ká má sì bẹ̀rù wípé kini àwọn èèyàn yíò sọ nípa wa tí a bá ṣe ohun tó bá Islam mu. A bẹ Allah kó yọ́nú sí wa.
Mubaarak Olayemi Ismail
Abu Muhsinah
BarakAllahu fihi. Kí Allah san yín ní ẹ̀san dáadáa.